ÌPADÀBỌ̀ ABÌJÀ ÀGBÉDÌDE EKILÉSÍÀ; ÈRÈ ÌṢỌ̀KAN KRISTẸNI

by Sammiecode

Ọ̀rẹ́ Kristi àti ajogún ìgbàlà bí àwa pẹ̀lú, a fi tayọ tayọ pè iwo pẹ̀lú ṣí àkójọpọ̀ àwọn tí a ti fi oore-ọ̀fẹ́ yàn láti di Ara Kristi (EKILESIA RẸ̀) nínú ayé pàápàá ní agbègbè yìí. Àǹfààní ńlá gbáà ni fún wa láti pè wá kúrò nínú gbogbo làálàá wa gbogbo àti Ìsá sókè sá sódò wa nínú ayé kí a leè wá gba ìsinmi tí Òun ti pèsè sílẹ̀ fún wa (Mátíù 11:28-29). A kò sì gbọdọ̀ se àìbìkítà fún ìpè ńlá yìí nítorí wípé gbogbo wa pátápátá ni a fi oore-ọ̀fẹ́ yìí fún ní àsìkò tiwa yìí.

Ìpè yìí ń wá sí wa bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé a kò mọ̀ nípa rẹ̀ tẹ́lẹ̀, sùgbón a ti pèsè ohun gbogbo sílẹ̀ fún wa àti wípé alẹ́ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ lẹ́ tán, ilẹ̀ sì ti ń ṣú lọ. Wàyí o, Ọlọ́run Baba fúnra Rẹ̀ ni ó rán wa jáde láti lọ kéde fún gbogbo àwọn arìnrìn-àjò lọ́nà wípé kí wọn kí ó tara sàsà yà síhìn-ín láti wa jẹ àsè ńlá tí a ti pèsè sílẹ̀ yìí (Mátíù 22:8-10. Lúùkù 14:21,23). Àmì ìdánilójú àkókò yí ni wípé gbogbo wa pátápátá tí a ti pè tí a sì ti jẹ́ ìpè yí ni a óò sọ ẹrù wúwo orí wa kalẹ̀ tí a ó ṣì fún ní ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀.

ÈTÒ ÀTI ÈTE ỌLỌ́RUN FÚN ÌPÈ YÌÍ

Kíni ìdí Pàtàkì tí a fi pè wá sí ibi irú ètò yìí? Ẹlòmíràn yíò rí ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aláìjámọ́ nǹkan, aláìyẹ àti ẹni àìtọ́ fún irú ògo yìí;  bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni àwọn ẹni ti ìgbàanì náà se rí pẹ̀lú. Kò sí ẹni tí ó yẹ fún irú ìpè tí ó lógo yìí, ṣùgbọ́n Ọlọ́run ń fẹ láti kọ́ Ara fún Ọmọ bíbí Rẹ̀ kan soso, Jésù Kristi. Òun ti fi Jésù Ọmọ Rẹ̀ se orí, wàyí ó, ńṣe ni Baba ń wá àkójọ àwọn ènìyàn láti jẹ́ Ara Rẹ̀. Àkójọpọ̀ àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni Òun pè ní EKILÉṢÍÀ gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ní Mátíù 16:18. Ètò Ọlọ́run ni láti gbé  ‘Orí’ tí í ṣe Kristi Jésù Omo Mímọ́ Rẹ̀ yí lé  ‘Ara’ tí Òun ń kó jọ yìí. Àpapọ̀  ‘Orí’ ati ‘Ara’ yìí ni yíò wá di KRISTI JÉSÙ  nínú ayé, pàápàá ní agbègbè k’agbègbè ibi tí a bá ti rí wọn ṣàjọ. Èyí ni a pè ní  èdè Gíríìkì ní ‘EKILÉSÍÀ’.

IṢẸ́ EKILÉSÍÀ YÌÍ

Ekilésíà yìí ni Ọlọ́run ti ṣe tán láti fi àṣẹ àti agbára ìṣàkóso àgbègbè k’ágbégbé, ìlú k’ilu, ilẹ̀ ọba kikí lẹ ọba tí a bá ti rí wọn lé lọ́wọ́. Àwọn ni yíò fa ìjọba Ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá sí irú agbègbè bẹ́ẹ̀. Àwọn ni yíò ní àṣẹ láti dè àti láti tú ní ayé (Mátíù 16:19. 18:18. Àìsáyà 22:22. Jòhánù 20:23. Jóòbù 12:14. Ìfihàn 3:7). Àǹfààní yìí ni Ekilesia ni ṣùgbọ́n tí a kò tíì leè loo láti ọjọ́ yì wá nítorí wípé Sátánì, ẹni ìfibú nì àti olùdènà ohun rere gbogbo ti dó ti Ìjọ Ọlọ́run láti ìgbà pípẹ́ wá ti ó sì ti mú wa ṣìnà tí a sì ti yà kúrò ní ojú ọ̀nà náà. Èyí ni ó fàá tí a kò fi leè dúró; àti ti ìjọba Ọlọ́run láàrín àwọn ọmọ ènìyàn fi di ahoro (Matiu 12:25). Èṣù ti fi ẹ̀mí ẹlẹ́yàmeyà àti ti àìṣọ̀kan ba tiwa jẹ́. A ti kó sí pàkúté rẹ̀ a sì ti ń jìyà yí láti ọjọ́ tí ó ti pẹ́ wá. Àkàrà tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ ni a ti fi fún àwọn ajá tí àwọn ọmọ sì ń kígbe ebi (Máàkù 7:27-28)! Àwọn ohun àjèjì ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé, ẹrú ń gun ẹṣin àní àwọn ọmọ aládé ń fi ẹsẹ̀ rìn! Ìwẹ̀fà ti di ọba lé àwọn àrólé l’órí! Àwọn ọmọ ẹlẹ́ran ti wá ń jẹ eegun, bẹ́ẹ̀ síni àwọn ọmọ alásọ̀ ti wá ń wọ àkísà bayìí. Èyí gan-an ni àwọn Ọ̀run ń gbé ojú agan sí báyìí. Àtúntò yìí sì ni Ọlọ́run ń gbìyànjú láti tún tò àti wípé nitori` ìdí pàtàkì yìí ni Ẹ̀mí-Mímọ́ ṣe ńlọgun Ìṣọ̀kan  fún gbogbo àwa tí a ti fi oore-ọ̀fẹ́ yàn. Èyí gan-an ni iṣẹ́ tí Ọlọ́run ń fẹ fi Ekilesia Rẹ̀  yí se ní àkókò yìí. Àwọn ohun tí a là kalẹ̀ wọ̀nyí kò ṣí ní àrọ́wọ́tó ìjọ ẹlẹ́yàmèyà lábẹ́ àkóso bí ó ti wù kí ó rí. Àwọn ọmọ ìjọ ẹlẹ́yàmèyà ìbá à lé ní igba tàbí kí ìfòróróyàn orí rẹ̀ máa jó bí iná, a kò fi fún-un láti ṣe àkóso ayé nítorí wipe ìpìlẹ̀ rẹ̀ kéré sí ohun tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ fún Ara-Kristi láti na ara Rẹ̀ lé (Aisaya 28:20).

OHUN TÍ ỌLỌ́RUN KÒ LỌ́wỌ́ Sí MỌ́

Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ sókè yìí, a gbọ́dọ̀ mọ̀ dájú wípé Ọlọ́run kò tún lọ́wọ́ sí dídá ìjọ ẹlẹ́yàmèyà kan sílẹ̀ mọ́, bẹẹni Ẹ̀mí-Mímọ́ ki yio gba wa láàyè lati tun padà sẹ́yìn. Ṣùgbọ́n Òun fúnra Rẹ̀, àní Ẹ̀mí-Mímó yíò gbé àwọn ìránṣẹ́ ẹni bí ọkàn Ọlọ́run dìde lẹ́ẹ̀kan si láti fi oúnjẹ tí ó dára tí yóò fún wa lókun bọ́ àwọn ènìyàn Rẹ̀. EẸnikẹ́ni kì yíò sì ṣe aláìní nítorí wípé ìgbà ìmúpadàbọ̀ sípò ni a wà yìí. Nítorí náà, a rọ gbogbo àwa tí a ti pè láti fi tọkàntọkàn bá Ọlọ́run rìn kí Òun leè ṣe ohun tí Ó ti múra tán láti ṣe, àní ní ìgbà tiwa yìí. Oore-ọ̀fẹ́ fún yín! Àmín.

You may also like

Leave a Comment